Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Gbogbo bàtà jagunjagun tí a ti lò lójú ogun àti gbogbo ẹ̀wù tí a yí nínú ẹ̀jẹ̀, ni yóò wà fún ìjóná, àti ohun èlò iná dídá.

Isaiah 9:5 in English

Isaiah 9:5 · Berean Standard Bible

For every trampling boot of battle and every garment rolled in blood will be burned as fuel for the fire.

Context

3Ìwọ ti sọ orílẹ̀-èdè di ńlá; wọ́n sì yọ̀ níwájú rẹ gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn ti í yọ ayọ̀ ìkórè, gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ti í yọ̀ nígbà tí à ń pín ìkógun. 4Nítorí gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí a ṣẹ́gun Midiani, ìwọ ti fọ́ ọ túútúú àjàgà ti ń pa wọ́n lẹ́rù, ọ̀pá tí ó dábùú èjìká wọn, ọ̀gọ aninilára wọn. 5Gbogbo bàtà jagunjagun tí a ti lò lójú ogun àti gbogbo ẹ̀wù tí a yí nínú ẹ̀jẹ̀, ni yóò wà fún ìjóná, àti ohun èlò iná dídá. 6Nítorí a bí ọmọ kan fún wa, a fi ọmọkùnrin kan fún wa, ìjọba yóò sì wà ní èjìká rẹ̀. A ó sì máa pè é ní Ìyanu Olùdámọ̀ràn, Ọlọ́run Alágbára, Baba ayérayé, Ọmọ ọba aládé Àlàáfíà. 7Ní ti gbígbòòrò Ìjọba rẹ̀ àti àlàáfíà rẹ̀ ni kì yóò ní ìpẹ̀kun. Yóò jẹ ọba lórí ìtẹ́ Dafidi àti lórí ẹ̀kún un rẹ̀ gbogbo, nípa ìfìdímúlẹ̀ àti ìgbéró rẹ̀, pẹ̀lú òtítọ́ àti òdodo láti ìgbà náà lọ àti títí láéláé. Ìtara Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni yóò mú èyí ṣẹ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.