Isaiah 8:6
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Nítorí pé àwọn ènìyàn yìí ti kọ omi Ṣiloa tí ń sàn jẹ́ẹ́jẹ́ sílẹ̀ tí wọ́n sì ń yọ̀ nínú Resini àti ọmọ Remaliah,
Isaiah 8:6 in English
Isaiah 8:6 · Berean Standard Bible
“Because this people has rejected the gently flowing waters of Shiloah and rejoiced in Rezin and the son of Remaliah,
Context
4Kí ọmọkùnrin náà tó mọ bí a ti ń sọ pé, ‘Baba mi’ tàbí ‘Ìyá mi,’ gbogbo ọrọ̀ Damasku àti ìkógun ti Samaria ni ọba àwọn Asiria yóò ti kó lọ.” 5Olúwa sì tún sọ fún mi pé, 6“Nítorí pé àwọn ènìyàn yìí ti kọ
omi Ṣiloa tí ń sàn jẹ́ẹ́jẹ́ sílẹ̀
tí wọ́n sì ń yọ̀ nínú Resini
àti ọmọ Remaliah, 7ǹjẹ́ nítorí náà kíyèsi i, Olúwa ń fa omi odò tí ó le,
tí ó sì pọ̀ wá sórí wọn,
àní, ọba Asiria àti gbogbo ògo rẹ̀,
yóò sì wá sórí gbogbo ọ̀nà odò rẹ̀,
yóò sì gun orí gbogbo bèbè rẹ̀, 8yóò sì gbá àárín Juda kọjá,
yóò sì ṣàn bò ó mọ́lẹ̀, yóò sì mú un dọ́rùn.
Nínà ìyẹ́ apá rẹ̀ yóò sì bo gbogbo ìbú ilẹ̀ rẹ̀,
ìwọ Emmanueli.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.