Isaiah 65:8
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Báyìí ni Olúwa wí: “Gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí oje sì tún wà nínú àpólà àjàrà tí àwọn ènìyàn sì wí pé, ‘Má ṣe bà á jẹ́, nítorí ìbùkún ń bẹ nínú rẹ̀,’ bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò ṣe nítorí ìránṣẹ́ mi; Èmi kì yóò pa gbogbo wọn run.
Isaiah 65:8 in English
Isaiah 65:8 · Berean Standard Bible
This is what the LORD says: “As the new wine is found in a cluster of grapes, and men say, ‘Do not destroy it, for it contains a blessing,’ so I will act on behalf of My servants; I will not destroy them all.
Context
6“Kíyèsi i, a ti kọ ọ́ síwájú mi,
Èmi kì yóò dákẹ́,
ṣùgbọ́n èmi yóò san án padà lẹ́kùnrẹ́rẹ́;
Èmi yóò san án padà sí àyà wọn 7àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín àti tàwọn baba yín,”
ni Olúwa wí.
“Nítorí pé wọ́n sun ẹbọ ní orí òkè ńlá
wọ́n sì ṣe ẹ̀gbin sí mi ní òkè kékeré,
Èmi yóò wọ́n ọ́n sí itan wọn
ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ẹ̀san ohun gbogbo tí wọ́n ṣe tẹ́lẹ̀.” 8Báyìí ni Olúwa wí:
“Gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí oje sì tún wà nínú àpólà àjàrà
tí àwọn ènìyàn sì wí pé, ‘Má ṣe bà á jẹ́,
nítorí ìbùkún ń bẹ nínú rẹ̀,’
bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò ṣe nítorí ìránṣẹ́ mi;
Èmi kì yóò pa gbogbo wọn run. 9Èmi yóò mú ìrandíran wá láti ìdílé Jakọbu,
àti láti Juda àwọn tí yóò jogún òkè ńlá mi wọ̀n-ọn-nì;
àwọn àyànfẹ́ ènìyàn mi yóò jogún wọn,
ibẹ̀ ni àwọn ìránṣẹ́ mi yóò sì gbé. 10Ṣaroni yóò di pápá oko fún ọ̀wọ́ ẹran,
àti àfonífojì Akori yóò di ibi ìsinmi fún agbo ẹran,
fún àwọn ènìyàn mi tí ó wá mi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.