Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín àti tàwọn baba yín,” ni Olúwa wí. “Nítorí pé wọ́n sun ẹbọ ní orí òkè ńlá wọ́n sì ṣe ẹ̀gbin sí mi ní òkè kékeré, Èmi yóò wọ́n ọ́n sí itan wọn ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ẹ̀san ohun gbogbo tí wọ́n ṣe tẹ́lẹ̀.”

Isaiah 65:7 in English

Isaiah 65:7 · Berean Standard Bible

both for your iniquities and for those of your fathers,” says the LORD. “Because they burned incense on the mountains and scorned Me on the hills, I will measure into their laps full payment for their former deeds.”

Context

5tí ó wí pé, ‘Ẹ sún mẹ́yìn; ẹ má wá sọ́dọ̀ mi, nítorí mo ti jẹ́ mímọ́ jù fún un yín!’ Àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ jẹ́ èéfín nínú ihò imú mi iná tí ń fi gbogbo ọjọ́ jó. 6“Kíyèsi i, a ti kọ ọ́ síwájú mi, Èmi kì yóò dákẹ́, ṣùgbọ́n èmi yóò san án padà lẹ́kùnrẹ́rẹ́; Èmi yóò san án padà sí àyà wọn 7àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín àti tàwọn baba yín,” ni Olúwa wí. “Nítorí pé wọ́n sun ẹbọ ní orí òkè ńlá wọ́n sì ṣe ẹ̀gbin sí mi ní òkè kékeré, Èmi yóò wọ́n ọ́n sí itan wọn ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ẹ̀san ohun gbogbo tí wọ́n ṣe tẹ́lẹ̀.” 8Báyìí ni Olúwa wí: “Gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí oje sì tún wà nínú àpólà àjàrà tí àwọn ènìyàn sì wí pé, ‘Má ṣe bà á jẹ́, nítorí ìbùkún ń bẹ nínú rẹ̀,’ bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò ṣe nítorí ìránṣẹ́ mi; Èmi kì yóò pa gbogbo wọn run. 9Èmi yóò mú ìrandíran wá láti ìdílé Jakọbu, àti láti Juda àwọn tí yóò jogún òkè ńlá mi wọ̀n-ọn-nì; àwọn àyànfẹ́ ènìyàn mi yóò jogún wọn, ibẹ̀ ni àwọn ìránṣẹ́ mi yóò sì gbé.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.