Isaiah 65:11
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ṣùgbọ́n fún ẹ̀yin tí ó kọ Olúwa sílẹ̀ tí ó sì gbàgbé òkè ńlá mímọ́ mi, tí ó tẹ́ tábìlì fún Gadi tí ẹ sì kún abọ́ pẹ̀lú ọtí wáìnì fún àtubọ̀tán,
Isaiah 65:11 in English
Isaiah 65:11 · Berean Standard Bible
But you who forsake the LORD, who forget My holy mountain, who set a table for Fortune * and fill bowls of mixed wine for Destiny,*
Context
9Èmi yóò mú ìrandíran wá láti ìdílé Jakọbu,
àti láti Juda àwọn tí yóò jogún òkè ńlá mi wọ̀n-ọn-nì;
àwọn àyànfẹ́ ènìyàn mi yóò jogún wọn,
ibẹ̀ ni àwọn ìránṣẹ́ mi yóò sì gbé. 10Ṣaroni yóò di pápá oko fún ọ̀wọ́ ẹran,
àti àfonífojì Akori yóò di ibi ìsinmi fún agbo ẹran,
fún àwọn ènìyàn mi tí ó wá mi. 11“Ṣùgbọ́n fún ẹ̀yin tí ó kọ Olúwa sílẹ̀
tí ó sì gbàgbé òkè ńlá mímọ́ mi,
tí ó tẹ́ tábìlì fún Gadi
tí ẹ sì kún abọ́ pẹ̀lú ọtí wáìnì fún àtubọ̀tán, 12Èmi yóò yà ọ́ sọ́tọ̀ fún idà,
àti pé ẹ̀yin yóò bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀ fún àwọn tí a pa;
nítorí mo pè, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò dáhùn.
Mo sọ̀rọ̀ ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò tẹ́tí sílẹ̀.
Ẹ̀yin ṣe búburú ní ojú mi
ẹ sì yan ohun tí ó bà mí lọ́kàn jẹ́.” 13Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí:
“Àwọn ìránṣẹ́ mi yóò jẹun;
ṣùgbọ́n ebi yóò máa pa ẹ̀yin,
àwọn ìránṣẹ́ mi yóò mu,
ṣùgbọ́n òǹgbẹ yóò máa gbẹ ẹ̀yin;
àwọn ìránṣẹ́ mi yóò ṣe àjọyọ̀,
ṣùgbọ́n a ó dójútì yin.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.