Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Èmi nìkan ti dá tẹ ìfúntí wáìnì; láti àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹnikẹ́ni kò sì wà pẹ̀lú mi. Mo tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ ní ìbínú mi mo sì tẹ̀ wọ́n rẹ́ ní ìrunú mi ẹ̀jẹ̀ wọn sì fọ́n sí aṣọ mi, mo sì da àbàwọ́n sí gbogbo aṣọ mi.

Isaiah 63:3 in English

Isaiah 63:3 · Berean Standard Bible

“I have trodden the winepress alone, and no one from the nations was with Me. I trampled them in My anger and trod them down in My fury; their blood spattered My garments, and all My clothes were stained.

Context

1Ta nì eléyìí tí ó Edomu wá, ti òun ti aṣọ àrẹpọ́n láti Bosra wá? Ta nì eléyìí, tí ó ní ògo nínú aṣọ rẹ̀, tí ó ń yan bọ̀ wá nínú ọláńlá agbára rẹ̀? “Èmi ni ẹni tí ó ń sọ̀rọ̀ nínú òdodo tí ó ní ipa láti gbàlà.” 2Èéṣe tí aṣọ yín fi pupa gẹ́gẹ́ bí i tàwọn tí ń ṣiṣẹ́ ní ìfúntí? 3“Èmi nìkan ti dá tẹ ìfúntí wáìnì; láti àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹnikẹ́ni kò sì wà pẹ̀lú mi. Mo tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ ní ìbínú mi mo sì tẹ̀ wọ́n rẹ́ ní ìrunú mi ẹ̀jẹ̀ wọn sì fọ́n sí aṣọ mi, mo sì da àbàwọ́n sí gbogbo aṣọ mi. 4Nítorí ọjọ́ ẹ̀san wà ní ọkàn mi àti pé ọdún ìràpadà mi ti dé. 5Mo wò, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan láti ṣe ìrànwọ́. Àyà fò mí pé ẹnikẹ́ni kò ṣèrànwọ́; nítorí náà apá mi ni ó ṣiṣẹ́ ìgbàlà fún mi àti ìrunú mi ni ó gbé mi ró.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.