Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ta nì eléyìí tí ó Edomu wá, ti òun ti aṣọ àrẹpọ́n láti Bosra wá? Ta nì eléyìí, tí ó ní ògo nínú aṣọ rẹ̀, tí ó ń yan bọ̀ wá nínú ọláńlá agbára rẹ̀? “Èmi ni ẹni tí ó ń sọ̀rọ̀ nínú òdodo tí ó ní ipa láti gbàlà.”

Isaiah 63:1 in English

Isaiah 63:1 · Berean Standard Bible

Who is this coming from Edom, from Bozrah with crimson-stained garments? Who is this robed in splendor, marching in the greatness of His strength? “It is I, proclaiming vindication,* mighty to save.”

Context

1Ta nì eléyìí tí ó Edomu wá, ti òun ti aṣọ àrẹpọ́n láti Bosra wá? Ta nì eléyìí, tí ó ní ògo nínú aṣọ rẹ̀, tí ó ń yan bọ̀ wá nínú ọláńlá agbára rẹ̀? “Èmi ni ẹni tí ó ń sọ̀rọ̀ nínú òdodo tí ó ní ipa láti gbàlà.” 2Èéṣe tí aṣọ yín fi pupa gẹ́gẹ́ bí i tàwọn tí ń ṣiṣẹ́ ní ìfúntí? 3“Èmi nìkan ti dá tẹ ìfúntí wáìnì; láti àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹnikẹ́ni kò sì wà pẹ̀lú mi. Mo tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ ní ìbínú mi mo sì tẹ̀ wọ́n rẹ́ ní ìrunú mi ẹ̀jẹ̀ wọn sì fọ́n sí aṣọ mi, mo sì da àbàwọ́n sí gbogbo aṣọ mi.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.