Isaiah 62:12
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
A ó sì pè wọ́n ní Ènìyàn Mímọ́, ẹni ìràpadà Olúwa; a ó sì máa pè ọ́ ní ìwákiri, ìlú tí a kì yóò kọ̀sílẹ̀.
Isaiah 62:12 in English
Isaiah 62:12 · Berean Standard Bible
And they will be called the Holy People, the Redeemed of The LORD; and you will be called Sought Out, A City Not Forsaken.
Context
10Ẹ kọjá, ẹ kọjá ní ẹnu ibodè náà!
Ẹ tún ọ̀nà ṣe fún àwọn ènìyàn.
Ẹ mọ ọ́n sókè, ṣe ojú ọ̀nà òpópó!
Ẹ ṣa òkúta kúrò.
Ẹ gbé àsíá sókè fún àwọn orílẹ̀-èdè. 11Olúwa ti ṣe ìkéde
títí dé òpin ilẹ̀ ayé:
“Ẹ sọ fún ọmọbìnrin Sioni pé,
‘Kíyèsi i, Olùgbàlà rẹ ń bọ̀!
Kíyèsi i, èrè ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀,
àti ẹ̀san rẹ̀ pẹ̀lú n tẹ̀lé e lẹ́yìn.’ ” 12A ó sì pè wọ́n ní Ènìyàn Mímọ́,
ẹni ìràpadà Olúwa;
a ó sì máa pè ọ́ ní ìwákiri,
ìlú tí a kì yóò kọ̀sílẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.