Isaiah 62:11
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Olúwa ti ṣe ìkéde títí dé òpin ilẹ̀ ayé: “Ẹ sọ fún ọmọbìnrin Sioni pé, ‘Kíyèsi i, Olùgbàlà rẹ ń bọ̀! Kíyèsi i, èrè ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀, àti ẹ̀san rẹ̀ pẹ̀lú n tẹ̀lé e lẹ́yìn.’ ”
Isaiah 62:11 in English
Isaiah 62:11 · Berean Standard Bible
Behold, the LORD has proclaimed to the ends of the earth, “Say to Daughter Zion: See, your Savior comes! Look, His reward is with Him, and His recompense goes before Him.”
Context
9ṣùgbọ́n àwọn tí ó bá kóórè rẹ̀ ni yóò jẹ ẹ́,
tí wọn ó sì yin Olúwa,
àti àwọn tí wọ́n bá kó àjàrà jọ ni wọn ó mú un,
nínú àgbàlá ilé mímọ́ mi.” 10Ẹ kọjá, ẹ kọjá ní ẹnu ibodè náà!
Ẹ tún ọ̀nà ṣe fún àwọn ènìyàn.
Ẹ mọ ọ́n sókè, ṣe ojú ọ̀nà òpópó!
Ẹ ṣa òkúta kúrò.
Ẹ gbé àsíá sókè fún àwọn orílẹ̀-èdè. 11Olúwa ti ṣe ìkéde
títí dé òpin ilẹ̀ ayé:
“Ẹ sọ fún ọmọbìnrin Sioni pé,
‘Kíyèsi i, Olùgbàlà rẹ ń bọ̀!
Kíyèsi i, èrè ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀,
àti ẹ̀san rẹ̀ pẹ̀lú n tẹ̀lé e lẹ́yìn.’ ” 12A ó sì pè wọ́n ní Ènìyàn Mímọ́,
ẹni ìràpadà Olúwa;
a ó sì máa pè ọ́ ní ìwákiri,
ìlú tí a kì yóò kọ̀sílẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.