Isaiah 60:3
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn orílẹ̀-èdè yóò wá sí ìmọ́lẹ̀ rẹ, àti àwọn ọba sí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ rẹ.
Isaiah 60:3 in English
Isaiah 60:3 · Berean Standard Bible
Nations will come to your light, and kings to the brightness of your dawn.
Context
1“Dìde, tànmọ́lẹ̀, nítorí ìmọ́lẹ̀ rẹ ti dé,
ògo Olúwa sì ràdàbò ọ́. 2Kíyèsi i, òkùnkùn bo ilẹ̀ ayé
òkùnkùn biribiri sì wà lórí àwọn ènìyàn,
ṣùgbọ́n Olúwa ràn bò ọ́
ògo rẹ̀ sì farahàn lórí i rẹ. 3Àwọn orílẹ̀-èdè yóò wá sí ìmọ́lẹ̀ rẹ,
àti àwọn ọba sí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ rẹ. 4“Gbé ojú rẹ sókè, kí o sì wò.
Gbogbo wọn ṣa ara jọ pọ̀, wọ́n sì wá sọ́dọ̀ rẹ;
àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin yóò wá láti ọ̀nà jíjìn,
àwọn ọmọ rẹ obìnrin ni a ó tọ́jú ní ẹ̀gbẹ́ rẹ. 5Nígbà náà ni ìwọ yóò wò tí ojú rẹ yóò máa dán,
ọkàn rẹ yó fò, yó sì kún fún ayọ̀;
ọrọ̀ inú Òkun ni a ó kò wá sọ́dọ̀ rẹ,
sí ọ̀dọ̀ rẹ ni ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè yóò wá.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.