Isaiah 58:8
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni ìmọ́lẹ̀ rẹ yóò tàn jáde bí òwúrọ̀ àti ìmúláradá rẹ yóò farahàn kíákíá; nígbà náà ni òdodo rẹ yóò sì lọ níwájú rẹ, ògo Olúwa yóò sì jẹ́ ààbò lẹ́yìn rẹ.
Isaiah 58:8 in English
Isaiah 58:8 · Berean Standard Bible
Then your light will break forth like the dawn, and your healing will come quickly. Your righteousness will go before you, and the glory of the LORD will be your rear guard.
Context
6“Ǹjẹ́ irú àwẹ̀ tí mo ti yàn kọ́ ni èyí:
láti já gbogbo ẹ̀wọ̀n àìṣòdodo
àti láti tú gbogbo okùn àjàgà,
láti tú gbogbo àwọn ti à ń ni lára sílẹ̀
àti láti fọ́ gbogbo àjàgà? 7Kì í ha á ṣe láti pín oúnjẹ yín fún àwọn tí ebi ń pa
àti láti pèsè ibùgbé fún àwọn òtòṣì tí ń rìn káàkiri.
Nígbà tí ẹ bá rí ẹni tí ó wà níhòhò, láti daṣọ bò ó,
àti láti má ṣe lé àwọn ìbátan yín sẹ́yìn? 8Nígbà náà ni ìmọ́lẹ̀ rẹ yóò tàn jáde bí òwúrọ̀
àti ìmúláradá rẹ yóò farahàn kíákíá;
nígbà náà ni òdodo rẹ yóò sì lọ níwájú rẹ,
ògo Olúwa yóò sì jẹ́ ààbò lẹ́yìn rẹ. 9Nígbà yìí ni ẹ̀yin yóò pè, tí Olúwa yóò sì dáhùn;
ẹ̀yin yóò kígbe fún ìrànlọ́wọ́, òun yóò sì wí pé, Èmi nìyí.
“Bí ìwọ bá mú àjàgà aninilára,
nínà ìka àlébù àti sísọ ọ̀rọ̀ asán kúrò láàrín rẹ, 10àti bí ẹ̀yin bá ná ara yín bí owó nítorí àwọn tí ebi ń pa
tí ẹ sì tẹ́ ìfẹ́ àwọn tí à ń ni lára lọ́rùn,
nígbà náà ni ìmọ́lẹ̀ yín yóò ràn nínú òkùnkùn,
àti òru yín yóò dàbí ọ̀sán gangan.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.