Isaiah 58:3
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọ́n wí pé, ‘Èéṣe tí àwa fi ń gbààwẹ̀, tí ìwọ kò sì tí ì rí? Èéṣe tí àwa fi rẹra wa sílẹ̀, tí ìwọ kò sì tí ì ṣe àkíyèsí?’ “Síbẹ̀síbẹ̀ ní ọjọ́ àwẹ̀ yín, ẹ̀yin ń ṣe bí ó ti wù yín ẹ sì ń pọ́n àwọn òṣìṣẹ́ yín gbogbo lójú.
Isaiah 58:3 in English
Isaiah 58:3 · Berean Standard Bible
“Why have we fasted, and You have not seen? Why have we humbled ourselves, and You have not noticed?” “Behold, on the day of your fast, you do as you please, and you oppress all your workers.
Context
1“Kígbe rẹ̀ sókè, má ṣe fàsẹ́yìn.
Gbé ohùn rẹ sókè bí i ti fèrè.
Jẹ́ kí ó di mí mọ̀ fún àwọn ènìyàn mi, ọ̀tẹ̀ wọn,
àti fún ilé Jakọbu ẹ̀ṣẹ̀ wọn. 2Nítorí ọjọ́ dé ọjọ́ ni wọ́n ń wá mi kiri;
wọ́n ṣe bí ẹni ní ìtara láti mọ ọ̀nà mi,
àfi bí ẹni pé wọ́n jẹ́ orílẹ̀-èdè kan tí ń ṣe ohun tí ó tọ̀nà
tí òun kò sì tí ì kọ àṣẹ Ọlọ́run rẹ̀.
Wọ́n ń béèrè lọ́wọ́ mi fún ìpinnu nìkan
wọ́n sì ṣe bí ẹni ń tara fún Ọlọ́run láti súnmọ́ ọ̀dọ̀ wọn. 3Wọ́n wí pé, ‘Èéṣe tí àwa fi ń gbààwẹ̀,
tí ìwọ kò sì tí ì rí?
Èéṣe tí àwa fi rẹra wa sílẹ̀,
tí ìwọ kò sì tí ì ṣe àkíyèsí?’
“Síbẹ̀síbẹ̀ ní ọjọ́ àwẹ̀ yín, ẹ̀yin ń ṣe bí ó ti wù yín
ẹ sì ń pọ́n àwọn òṣìṣẹ́ yín gbogbo lójú. 4Àwẹ̀ yín sì parí nínú ìjà àti asọ̀,
àti lílu ọmọnìkejì ẹni pa pẹ̀lú ìkùùkuu.
Ẹ̀yin kò le è gbààwẹ̀ bí ẹ ti ń ṣe lónìí
kí ẹ sì retí kí a gbọ́ ohùn un yín ní ibi gíga. 5Ǹjẹ́ èyí ha ni irú àwẹ̀ tí mo yàn bí,
ọjọ́ kan ṣoṣo fún ènìyàn láti rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀?
Ó ha jẹ pe kí ènìyàn tẹ orí rẹ̀ ba bí i koríko lásán ni bí
àti sísùn nínú aṣọ ọ̀fọ̀ àti eérú?
Ṣé ohun tí ẹ̀ ń pè ní àwẹ̀ nìyí,
ọjọ́ ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.