Isaiah 53:11
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Lẹ́yìn ìpọ́njú ẹ̀mí rẹ̀, òun yóò rí ìmọ́lẹ̀, ààyè yóò sì tẹ́ ẹ lọ́rùn; nípa ìmọ̀ rẹ̀ ìránṣẹ́ mi olódodo yóò dá ọ̀pọ̀lọpọ̀ láre, Òun ni yóò sì ru àìṣedéédéé wọn.
Isaiah 53:11 in English
Isaiah 53:11 · Berean Standard Bible
After the anguish of His soul, He will see the light of life * and be satisfied. By His knowledge My righteous Servant will justify many, and He will bear their iniquities.
Context
9A fún un ní ibojì pẹ̀lú àwọn ìkà,
àti pẹ̀lú àwọn ọlọ́rọ̀ ní ikú rẹ̀,
bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò hùwà jàgídíjàgan kan,
tàbí kí a rí ẹ̀tàn kan ní ẹnu rẹ̀. 10Síbẹ̀, ó wu Olúwa láti pa á lára
àti láti mú kí ó jìyà,
bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Olúwa fi ayé rẹ̀
fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀,
Òun yóò rí àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ àti ọjọ́ ayé
rẹ̀ yóò pẹ́ títí,
àti ète Olúwa ni yóò gbèrú ní ọwọ́ rẹ̀. 11Lẹ́yìn ìpọ́njú ẹ̀mí rẹ̀,
òun yóò rí ìmọ́lẹ̀, ààyè yóò sì tẹ́ ẹ lọ́rùn;
nípa ìmọ̀ rẹ̀ ìránṣẹ́ mi olódodo yóò dá ọ̀pọ̀lọpọ̀ láre,
Òun ni yóò sì ru àìṣedéédéé wọn. 12Nítorí náà èmi yóò fún un ní ìpín pẹ̀lú àwọn ẹni ńlá
òun yóò sì pín ìkógun pẹ̀lú àwọn alágbára,
nítorí pé òun jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ fún ikú,
tí a sì kà á mọ́ àwọn alárékọjá.
Nítorí ó ru ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀,
ó sì ṣe ìlàjà fún àwọn alárékọjá.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.