Isaiah 52:14
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gẹ́gẹ́ bí a ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí wọ́n ń bu ọlá fún un— ìwò ojú rẹ ni a ti bàjẹ́ kọjá ti ẹnikẹ́ni àti ìrísí rẹ̀ ní a ti bàjẹ́ kọjá ohun tí ènìyàn ń fẹ́.
Isaiah 52:14 in English
Isaiah 52:14 · Berean Standard Bible
Just as many were appalled at Him *— His appearance was disfigured beyond that of any man, and His form was marred beyond human likeness—
Context
12Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kì yóò yára kúrò
tàbí kí ẹ sáré lọ;
nítorí Olúwa ni yóò síwájú yín lọ,
Ọlọ́run Israẹli ni yóò sì ṣe ààbò lẹ́yìn ín yín. 13Kíyèsi i, ìránṣẹ́ mi yóò hùwà ọlọ́gbọ́n;
òun ni a ó gbé sókè tí a ó sì gbéga
a ó sì gbé e lékè gidigidi. 14Gẹ́gẹ́ bí a ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí wọ́n ń bu ọlá fún un—
ìwò ojú rẹ ni a ti bàjẹ́ kọjá ti ẹnikẹ́ni àti ìrísí rẹ̀ ní a ti bàjẹ́ kọjá ohun tí ènìyàn ń fẹ́. 15Bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣe bomirin àwọn orílẹ̀-èdè ká,
àwọn ọba yóò sì pa ẹnu wọn mọ́ nítorí rẹ̀.
Nítorí ohun tí a kò sọ fún wọn, wọn yóò rí i,
àti ohun tí wọn kò tí ì gbọ́, ni yóò sì yé wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.