Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Olúwa yóò ṣí apá mímọ́ rẹ̀ sílẹ̀ ní ojú gbogbo orílẹ̀-èdè, àti gbogbo òpin ilẹ̀ ayé yóò rí ìgbàlà Ọlọ́run wa.

Isaiah 52:10 in English

Isaiah 52:10 · Berean Standard Bible

The LORD has bared His holy arm in the sight of all the nations; all the ends of the earth will see the salvation of our God.

Context

8Tẹ́tí sílẹ̀! Àwọn olùṣọ́ rẹ gbé ohùn wọn sókè wọ́n kígbe papọ̀ fún ayọ̀. Nígbà tí Olúwa padà sí Sioni, wọn yóò rí i pẹ̀lú ojú u wọn. 9Ẹ bú sí orin ayọ̀ papọ̀, ẹ̀yin ahoro Jerusalẹmu, nítorí Olúwa ti tu àwọn ènìyàn rẹ̀ nínú, ó sì ti ra Jerusalẹmu padà. 10Olúwa yóò ṣí apá mímọ́ rẹ̀ sílẹ̀ ní ojú gbogbo orílẹ̀-èdè, àti gbogbo òpin ilẹ̀ ayé yóò rí ìgbàlà Ọlọ́run wa. 11Ẹ túká, ẹ túká, ẹ jáde kúrò níhìn-ín yìí! Ẹ má fọwọ́ kan ohun àìmọ́ kan! Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀ kí ẹ sì di mímọ́, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé ohun èlò Olúwa. 12Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kì yóò yára kúrò tàbí kí ẹ sáré lọ; nítorí Olúwa ni yóò síwájú yín lọ, Ọlọ́run Israẹli ni yóò sì ṣe ààbò lẹ́yìn ín yín.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.