Isaiah 51:9
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Dìde, dìde! Kí o sì wọ ara rẹ ní agbára ìwọ apá Olúwa; dìde gẹ́gẹ́ bí i ti ọjọ́ ìgbà n nì, àti gẹ́gẹ́ bí i ti ìran àtijọ́. Ìwọ kọ́ lo ké Rahabu sí wẹ́wẹ́ tí o sì fa ẹ̀mí búburú ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ?
Isaiah 51:9 in English
Isaiah 51:9 · Berean Standard Bible
Awake, awake, put on strength, O arm of the LORD. Wake up as in days past, as in generations of old. Was it not You who cut Rahab to pieces, who pierced through the dragon?
Context
7“Ẹ gbọ́ mi, ẹ̀yin tí ó mọ ohun òtítọ́,
ẹ̀yin ènìyàn tí ó ní òfin mi ní àyà yín.
Ẹ má ṣe bẹ̀rù ẹ̀gàn àwọn ènìyàn
tàbí kí ẹ̀rù èébú wọn já a yín láyà. 8Nítorí kòkòrò yóò mú wọn lá bí aṣọ,
ìdin yóò sì mú wọn jẹ bí ẹ̀gbọ̀n òwú.
Ṣùgbọ́n òdodo mi yóò wà títí ayérayé,
àti ìgbàlà mi láti ìrandíran.” 9Dìde, dìde! Kí o sì wọ ara rẹ ní agbára
ìwọ apá Olúwa;
dìde gẹ́gẹ́ bí i ti ọjọ́ ìgbà n nì,
àti gẹ́gẹ́ bí i ti ìran àtijọ́.
Ìwọ kọ́ lo ké Rahabu sí wẹ́wẹ́
tí o sì fa ẹ̀mí búburú ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ? 10Ìwọ kọ́ ni ó gbẹ omi Òkun bí
àti àwọn omi inú ọ̀gbun,
tí o sì ṣe ọ̀nà nínú ìsàlẹ̀ Òkun
tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ẹni ìràpadà yóò fi le là á kọjá? 11Àwọn ẹni ìràpadà Olúwa yóò padà wá.
Wọn yóò wọ Sioni wá pẹ̀lú orin kíkọ;
ayọ̀ ayérayé ni yóò sì bo orí wọn.
Ayọ̀ àti inú dídùn yóò sì bà lé wọn
ìbànújẹ́ àti ìtìjú yóò sì sá kúrò.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.