Isaiah 51:7
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ẹ gbọ́ mi, ẹ̀yin tí ó mọ ohun òtítọ́, ẹ̀yin ènìyàn tí ó ní òfin mi ní àyà yín. Ẹ má ṣe bẹ̀rù ẹ̀gàn àwọn ènìyàn tàbí kí ẹ̀rù èébú wọn já a yín láyà.
Isaiah 51:7 in English
Isaiah 51:7 · Berean Standard Bible
Listen to Me, you who know what is right, you people with My law in your hearts: Do not fear the scorn of men; do not be broken by their insults.
Context
5Òdodo mi ń bọ̀ wá kíkankíkan,
ìgbàlà mi ń bọ̀ lójú ọ̀nà,
àti apá mi yóò sì mú ìdájọ́ wá
sí àwọn orílẹ̀-èdè.
Àwọn erékùṣù yóò wò mí
wọn yóò sì dúró ní ìrètí fún apá mi. 6Gbé ojú rẹ sókè sí àwọn ọ̀run,
wo ilẹ̀ ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀;
àwọn ọ̀run yóò pòórá bí èéfín,
ilẹ̀ yóò sì gbó bí ẹ̀wù
àwọn olùgbé inú rẹ̀ yóò kú gẹ́gẹ́ bí àwọn eṣinṣin.
Ṣùgbọ́n ìgbàlà mi yóò wà títí láé,
òdodo mi kì yóò yẹ̀ láé. 7“Ẹ gbọ́ mi, ẹ̀yin tí ó mọ ohun òtítọ́,
ẹ̀yin ènìyàn tí ó ní òfin mi ní àyà yín.
Ẹ má ṣe bẹ̀rù ẹ̀gàn àwọn ènìyàn
tàbí kí ẹ̀rù èébú wọn já a yín láyà. 8Nítorí kòkòrò yóò mú wọn lá bí aṣọ,
ìdin yóò sì mú wọn jẹ bí ẹ̀gbọ̀n òwú.
Ṣùgbọ́n òdodo mi yóò wà títí ayérayé,
àti ìgbàlà mi láti ìrandíran.” 9Dìde, dìde! Kí o sì wọ ara rẹ ní agbára
ìwọ apá Olúwa;
dìde gẹ́gẹ́ bí i ti ọjọ́ ìgbà n nì,
àti gẹ́gẹ́ bí i ti ìran àtijọ́.
Ìwọ kọ́ lo ké Rahabu sí wẹ́wẹ́
tí o sì fa ẹ̀mí búburú ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.