Isaiah 51:23
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi yóò fi lé àwọn apọ́nilójú rẹ lọ́wọ́, àwọn tí ó wí fún ọ pé, ‘Dọ̀bálẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí a ó fi máa rìn lórí rẹ.’ Ìwọ náà ṣe ẹ̀yìn rẹ gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òpópónà láti máa rìn lórí i rẹ̀.”
Isaiah 51:23 in English
Isaiah 51:23 · Berean Standard Bible
I will place it in the hands of your tormentors, who told you: ‘Lie down, so we can walk over you,’ so that you made your back like the ground, like a street to be traversed.”
Context
21Nítorí náà ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yin tí a ti ṣẹ́ níṣẹ̀ẹ́,
tí ọtí ń pa, ṣùgbọ́n kì í ṣe fún wáìnì. 22Ohun tí Olúwa Olódùmarè yín wí nìyìí,
Ọlọ́run rẹ, ẹni tí ó ń pa ènìyàn rẹ̀ mọ́,
“Kíyèsi i, mo ti mú un kúrò ní ọwọ́ rẹ
ago tí ó mú ọ ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n;
láti inú ago náà, ẹ̀kún ìbínú mi,
ni ìwọ kì yóò mu mọ́. 23Èmi yóò fi lé àwọn apọ́nilójú rẹ lọ́wọ́,
àwọn tí ó wí fún ọ pé,
‘Dọ̀bálẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí a ó fi máa rìn lórí rẹ.’
Ìwọ náà ṣe ẹ̀yìn rẹ gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀
gẹ́gẹ́ bí òpópónà láti máa rìn lórí i rẹ̀.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.