Isaiah 50:3
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi fi òkùnkùn bo sánmọ̀ mo sì fi aṣọ ọ̀fọ̀ ṣe ìbòrí rẹ̀.”
Isaiah 50:3 in English
Isaiah 50:3 · Berean Standard Bible
I clothe the heavens in black and make sackcloth their covering.”
Context
1Ohun tí Olúwa wí nìyìí:
“Níbo ni ìwé-ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀ ìyá rẹ wà
èyí tí mo fi lé e lọ?
Tàbí èwo nínú àwọn olùyánilówó mi
ni mo tà ọ́ fún?
Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ni a fi tà ọ́;
nítorí àìṣedéédéé rẹ ni a fi lé ìyá rẹ lọ. 2Nígbà tí mo wá, èéṣe tí a kò fi rí ẹnìkan?
Nígbà tí mo pè, èéṣe tí kò fi sí ẹnìkan láti dáhùn?
Ọwọ́ mi a kúrú láti gbà ọ́?
Èmi kò ha ní agbára láti gbà ọ́ bí?
Nípa ìbáwí lásán, Èmi gbẹ omi òkun,
Èmi yí àwọn odò sí aṣálẹ̀;
àwọn ẹja wọn rà fún àìsí omi
wọ́n sì kú fún òǹgbẹ. 3Èmi fi òkùnkùn bo sánmọ̀
mo sì fi aṣọ ọ̀fọ̀ ṣe ìbòrí rẹ̀.” 4Olúwa Olódùmarè ti fún mi ni ahọ́n tí a fi iṣẹ́ rán,
láti mọ àwọn ọ̀rọ̀ tí ó lè gbé àwọn aláàárẹ̀ ró.
O jí mi láràárọ̀,
o jí etí mi láti gbọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí à ń kọ́. 5Olúwa Olódùmarè ti ṣí mi ní etí,
bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ṣọ̀tẹ̀ rí;
Èmi kò sì padà sẹ́yìn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.