Isaiah 50:5
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Olúwa Olódùmarè ti ṣí mi ní etí, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ṣọ̀tẹ̀ rí; Èmi kò sì padà sẹ́yìn.
Isaiah 50:5 in English
Isaiah 50:5 · Berean Standard Bible
The Lord GOD has opened My ears, and I have not been rebellious, nor have I turned back.
Context
3Èmi fi òkùnkùn bo sánmọ̀
mo sì fi aṣọ ọ̀fọ̀ ṣe ìbòrí rẹ̀.” 4Olúwa Olódùmarè ti fún mi ni ahọ́n tí a fi iṣẹ́ rán,
láti mọ àwọn ọ̀rọ̀ tí ó lè gbé àwọn aláàárẹ̀ ró.
O jí mi láràárọ̀,
o jí etí mi láti gbọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí à ń kọ́. 5Olúwa Olódùmarè ti ṣí mi ní etí,
bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ṣọ̀tẹ̀ rí;
Èmi kò sì padà sẹ́yìn. 6Mo ṣí ẹ̀yìn mi sílẹ̀ fún àwọn tí ó ń nà mí,
àti ẹ̀rẹ̀kẹ́ mi fún àwọn tí ń fa irùngbọ̀n mi;
Èmi kò fi ojú mi pamọ́
kúrò lọ́wọ́ ẹlẹ́yà àti ìyọṣùtì sí. 7Nítorí Olúwa Olódùmarè ràn mí lọ́wọ́,
a kì yóò dójútì mí.
Nítorí náà ni mo ṣe gbé ojú mi ró bí òkúta akọ
èmi sì mọ pé, ojú kò ní tì mí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.