Isaiah 49:2
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó ṣe ẹnu mi bí idà tí a pọ́n, ní abẹ́ òjìji ọwọ́ rẹ̀ ni ó ti pa mí mọ́: ó ṣe mí ní ọfà tí a ti dán, ó sì fi mí pamọ́ sínú àpò rẹ̀.
Isaiah 49:2 in English
Isaiah 49:2 · Berean Standard Bible
He made My mouth like a sharp sword; He hid Me in the shadow of His hand. He made Me like a polished arrow; He hid Me in His quiver.
Context
1Tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin erékùṣù:
gbọ́ èyí, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè jíjìnnà réré:
kí a tó bí mi Olúwa ti pè mí;
láti ìgbà bíbí mi ni ó ti dá orúkọ mi. 2Ó ṣe ẹnu mi bí idà tí a pọ́n,
ní abẹ́ òjìji ọwọ́ rẹ̀ ni ó ti pa mí mọ́:
ó ṣe mí ní ọfà tí a ti dán,
ó sì fi mí pamọ́ sínú àpò rẹ̀. 3Ó sọ fún mi pé, “Ìránṣẹ́ mi ni ìwọ í ṣe,
Israẹli nínú ẹni tí n ó ti fi ògo mi hàn.” 4Ṣùgbọ́n èmi sọ pé, “Mo ti ṣe wàhálà lórí asán;
mo ti lo gbogbo ipá mi lórí asán àti ìmúlẹ̀mófo.
Síbẹ̀síbẹ̀ ohun tí ó tọ́ sí mi ṣì wà lọ́wọ́ Olúwa,
èrè mi sì ń bẹ pẹ̀lú Ọlọ́run mi.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.