Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èyí ni ohun tí Olúwa wí, Olùdáǹdè rẹ, Ẹni Mímọ́ Israẹli: “Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ, tí ó kọ́ ọ ní ohun tí ó dára fún ọ, tí ó tọ́ ọ ṣọ́nà tí ó yẹ kí o máa rìn.

Isaiah 48:17 in English

Isaiah 48:17 · Berean Standard Bible

Thus says the LORD your Redeemer, the Holy One of Israel: “I am the LORD your God, who teaches you for your benefit, who directs you in the way you should go.

Context

15Èmi, àní Èmi ló ti sọ̀rọ̀; bẹ́ẹ̀ ni, mo ti pè é. Èmi yóò mú un wá, òun yóò sì ṣe àṣeyọrí nínú ìrìnàjò rẹ̀. 16“Ẹ súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi kí ẹ sì dẹtí sí èyí: “Láti ìgbà ìkéde àkọ́kọ́ èmi kò sọ̀rọ̀ ní ìkọ̀kọ̀; ní àsìkò tí ó sì ṣẹlẹ̀, Èmi wà níbẹ̀.” Àti ní àkókò yìí, Olúwa Olódùmarè ni ó ti rán mi, pẹ̀lú ẹ̀mí rẹ̀. 17Èyí ni ohun tí Olúwa wí, Olùdáǹdè rẹ, Ẹni Mímọ́ Israẹli: “Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ, tí ó kọ́ ọ ní ohun tí ó dára fún ọ, tí ó tọ́ ọ ṣọ́nà tí ó yẹ kí o máa rìn. 18Bí ó bá ṣe pé ìwọ bá ti tẹ́tí sílẹ̀ sí àṣẹ mi, àlàáfíà rẹ kì bá ti dàbí ì ti odò, àti òdodo rẹ bí ìgbì Òkun. 19Àwọn ọmọ rẹ ìbá ti dàbí iyanrìn, àwọn ọmọ yín bí i hóró ọkà tí a kò lè kà tán; orúkọ wọn ni a kì yóò ké kúrò tàbí kí a pa wọ́n run níwájú mi.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.