Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Lóòótọ́ wọ́n dàbí ìṣẹ́pẹ́ igi; iná ni yóò jó wọn dànù. Wọn kò kúkú lè gba ara wọn là lọ́wọ́ agbára iná náà. Kò sí èédú láti mú ara ẹnikẹ́ni gbóná níhìn-ín kò sí iná tí ènìyàn le jókòó tì.

Isaiah 47:14 in English

Isaiah 47:14 · Berean Standard Bible

Surely they are like stubble; the fire will burn them up. They cannot deliver themselves from the power of the flame. There will be no coals to warm them or fire to sit beside.

Context

12“Tẹ̀síwájú nígbà náà, pẹ̀lú àfọ̀ṣẹ rẹ àti pẹ̀lú ìwà oṣó rẹ gbogbo, tí o ti ń ṣiṣẹ́ fún láti ìgbà èwe rẹ wá. Bóyá o le è ṣàṣeyọrí, bóyá o le è dá rúgúdù sílẹ̀. 13Gbogbo ìmọ̀ràn tí o ti gbà ni ó ti sọ ọ́ di akúrẹtẹ̀! Jẹ́ kí àwọn awòràwọ̀ rẹ bọ́ síwájú, àwọn awòràwọ̀ tí wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀ láti oṣù dé oṣù, jẹ́ kí wọ́n gbà ọ́ lọ́wọ́ ohun tí ó ń bọ̀ wá bá ọ. 14Lóòótọ́ wọ́n dàbí ìṣẹ́pẹ́ igi; iná ni yóò jó wọn dànù. Wọn kò kúkú lè gba ara wọn là lọ́wọ́ agbára iná náà. Kò sí èédú láti mú ara ẹnikẹ́ni gbóná níhìn-ín kò sí iná tí ènìyàn le jókòó tì. 15Gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe fún ọ nìyìí gbogbo èyí ní o tí ṣíṣẹ́ pẹ̀lú u rẹ̀ tí o sì ti ń rù kiri láti ìgbà èwe. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ń lọ nínú àṣìṣe rẹ̀; kò sí ẹyọ ẹnìkan tí ó lè gbà ọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.