Isaiah 47:12
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Tẹ̀síwájú nígbà náà, pẹ̀lú àfọ̀ṣẹ rẹ àti pẹ̀lú ìwà oṣó rẹ gbogbo, tí o ti ń ṣiṣẹ́ fún láti ìgbà èwe rẹ wá. Bóyá o le è ṣàṣeyọrí, bóyá o le è dá rúgúdù sílẹ̀.
Isaiah 47:12 in English
Isaiah 47:12 · Berean Standard Bible
So take your stand with your spells and with your many sorceries, with which you have wearied yourself from your youth. Perhaps you will succeed; perhaps you will inspire terror!
Context
10Ìwọ ti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìwà ìkà rẹ
ó sì ti wí pé, ‘Kò sí ẹni tí ó rí mi?’
Ọgbọ́n àti òye rẹ ti ṣì ọ́ lọ́nà
nígbà tí o wí fún ara rẹ pé,
‘Èmi ni, kò sí ẹlòmíràn lẹ́yìn mi.’ 11Ìparun yóò dé bá ọ
bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì yóò mọ ọ̀nà láti ré e kúrò.
Àjálù kan yóò ṣubú lù ọ́
tí o kì yóò le è fi ètùtù ré kúrò;
òfò kan tí o kò le faradà ni
yóò wá lójijì sí oríì rẹ. 12“Tẹ̀síwájú nígbà náà, pẹ̀lú àfọ̀ṣẹ rẹ
àti pẹ̀lú ìwà oṣó rẹ gbogbo,
tí o ti ń ṣiṣẹ́ fún láti ìgbà èwe rẹ wá.
Bóyá o le è ṣàṣeyọrí,
bóyá o le è dá rúgúdù sílẹ̀. 13Gbogbo ìmọ̀ràn tí o ti gbà ni
ó ti sọ ọ́ di akúrẹtẹ̀!
Jẹ́ kí àwọn awòràwọ̀ rẹ bọ́ síwájú,
àwọn awòràwọ̀ tí wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀
láti oṣù dé oṣù,
jẹ́ kí wọ́n gbà ọ́ lọ́wọ́ ohun tí ó ń bọ̀ wá bá ọ. 14Lóòótọ́ wọ́n dàbí ìṣẹ́pẹ́ igi;
iná ni yóò jó wọn dànù.
Wọn kò kúkú lè gba ara wọn là
lọ́wọ́ agbára iná náà.
Kò sí èédú láti mú ara ẹnikẹ́ni gbóná
níhìn-ín kò sí iná tí ènìyàn le jókòó tì.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.