Isaiah 45:2
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi yóò lọ síwájú rẹ, Èmi ó sì tẹ́ àwọn òkè ńlá pẹrẹsẹ Èmi yóò fọ gbogbo ẹnu-ọ̀nà idẹ èmi ó sì gé ọ̀pá irin.
Isaiah 45:2 in English
Isaiah 45:2 · Berean Standard Bible
“I will go before you and level the mountains;* I will break down the gates of bronze and cut through the bars of iron.
Context
1“Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún ẹni òróró rẹ̀,
sí Kirusi, ọwọ́ ọ̀tún ẹni tí mo dì mú
láti dojú àwọn orílẹ̀-èdè bolẹ̀ níwájú rẹ̀
àti láti gba ohun ìjà àwọn ọba lọ́wọ́ wọn,
láti ṣí àwọn ìlẹ̀kùn níwájú rẹ̀
tí ó fi jẹ́ pé a kì yóò ti àwọn ẹnu-ọ̀nà. 2Èmi yóò lọ síwájú rẹ,
Èmi ó sì tẹ́ àwọn òkè ńlá pẹrẹsẹ
Èmi yóò fọ gbogbo ẹnu-ọ̀nà idẹ
èmi ó sì gé ọ̀pá irin. 3Èmi yóò sì fún ọ ní àwọn ọrọ̀ ibi òkùnkùn,
ọrọ̀ tí a kó pamọ́ sí àwọn ibi tí ó fi ara sin,
tó bẹ́ẹ̀ tí ìwọ yóò fi mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa,
Ọlọ́run Israẹli, ẹni tí ó pè ọ́ pẹ̀lú orúkọ rẹ. 4Nítorí Jakọbu ìránṣẹ́ mi
àti Israẹli ẹni tí mo yàn,
Mo pè ọ́ pẹ̀lú orúkọ rẹ,
mo sì gbé oyè kan kà ọ́ lórí
bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ kò gbà mí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.