Isaiah 43:22
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Síbẹ̀síbẹ̀ ìwọ kò tí ì ké pè mí, ìwọ Jakọbu, àárẹ̀ kò tí ì mú ọ nítorí mi ìwọ Israẹli.
Isaiah 43:22 in English
Isaiah 43:22 · Berean Standard Bible
But you have not called on Me, O Jacob, because you have grown weary of Me, O Israel.
Context
20Àwọn ẹhànnà ẹranko bọ̀wọ̀ fún mi,
àwọn ajáko àti àwọn òwìwí,
nítorí pé mo pèsè omi nínú aṣálẹ̀
àti odò nínú ilẹ̀ sísá,
láti fi ohun mímu fún àwọn ènìyàn mi, àyànfẹ́ mi, 21àwọn ènìyàn tí mo dá fún ara mi
kí wọn kí ó lè kéde ìyìn mi. 22“Síbẹ̀síbẹ̀ ìwọ kò tí ì ké pè mí, ìwọ Jakọbu,
àárẹ̀ kò tí ì mú ọ nítorí mi ìwọ Israẹli. 23Ìwọ kò tí ì mú àgùntàn wá fún mi fún ẹbọ sísun,
tàbí kí o bọ̀wọ̀ fún mi pẹ̀lú ẹbọ rẹ.
Èmi kò tí ì wàhálà rẹ pẹ̀lú ọrẹ ìyẹ̀fun
tàbí kí n dààmú rẹ pẹ̀lú ìbéèrè fún tùràrí. 24Ìwọ kò tí ì ra kalamusi olóòórùn dídùn fún mi,
tàbí kí o da ọ̀rá ẹbọ rẹ bò mí.
Ṣùgbọ́n ẹ ti wàhálà mi pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ yín
ẹ sì ti dààmú mi pẹ̀lú àìṣedéédéé yín.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.