Isaiah 42:17
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé òrìṣà, tí wọ́n wí fún ère pé, ‘Ẹ̀yin ni Ọlọ́run wa,’ ni a ó dá padà pẹ̀lú ìtìjú.
Isaiah 42:17 in English
Isaiah 42:17 · Berean Standard Bible
But those who trust in idols and say to molten images, ‘You are our gods!’ will be turned back in utter shame.
Context
15Èmi yóò sọ òkè ńlá àti kékeré di ahoro
tí n ó sì gbẹ gbogbo ewéko rẹ̀ dànù,
Èmi yóò sọ àwọn odò di erékùṣù
n ó sì gbẹ àwọn adágún. 16Èmi yóò tọ àwọn afọ́jú ní ọ̀nà tí wọn kò tí ì mọ̀,
ní ipa ọ̀nà tí ó ṣàjèjì sí wọn ni èmi yóò tọ́ wọn lọ;
Èmi yóò sọ òkùnkùn di ìmọ́lẹ̀ níwájú wọn
àti ibi pálapàla ni èmi ó sọ di kíkúnná.
Àwọn nǹkan tí máa ṣe nìyìí;
Èmi kì yóò kọ̀ wọ́n sílẹ̀. 17Ṣùgbọ́n àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé òrìṣà,
tí wọ́n wí fún ère pé, ‘Ẹ̀yin ni Ọlọ́run wa,’
ni a ó dá padà pẹ̀lú ìtìjú. 18“Gbọ́, ìwọ adití,
wò ó, ìwọ afọ́jú, o sì rí! 19Ta ló fọ́jú bí kò ṣe ìránṣẹ́ mi,
àti odi gẹ́gẹ́ bí oníṣẹ́ tí mo rán?
Ta ni ó fọ́jú gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a fi jìnmí,
ó fọ́jú gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Olúwa?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.