Isaiah 4:2
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ní ọjọ́ náà, ẹ̀ka Olúwa yóò ní ẹwà àti ògo, èso ilẹ̀ náà yóò sì jẹ́ ìgbéraga àti ògo àwọn ti ó sálà ní Israẹli.
Isaiah 4:2 in English
Isaiah 4:2 · Berean Standard Bible
On that day the Branch of the LORD will be beautiful and glorious, and the fruit of the land will be the pride and glory of Israel’s survivors.
Context
1Ní ọjọ́ náà, obìnrin méje
yóò dì mọ́ ọkùnrin kan
yóò sì wí pé, “Àwa ó máa jẹ oúnjẹ ara wa
a ó sì pèsè aṣọ ara wa;
sá à jẹ́ kí a máa fi orúkọ rẹ̀ pè wá.
Mú ẹ̀gàn wa kúrò!” 2Ní ọjọ́ náà, ẹ̀ka Olúwa yóò ní ẹwà àti ògo, èso ilẹ̀ náà yóò sì jẹ́ ìgbéraga àti ògo àwọn ti ó sálà ní Israẹli. 3Àwọn tí ó ṣẹ́kù ní Sioni, àwọn tí o kù ní Jerusalẹmu, ni a ó pè ní mímọ́, orúkọ àwọn ẹni tí a kọ mọ́ àwọn alààyè ní Jerusalẹmu. 4Olúwa yóò wẹ ẹ̀gbin àwọn obìnrin Sioni kúrò yóò sì fọ gbogbo àbàwọ́n ẹ̀jẹ̀ kúrò ní Jerusalẹmu pẹ̀lú ẹ̀mí ìdájọ́ àti ẹ̀mí iná.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.