Isaiah 39:3
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Lẹ́yìn náà wòlíì Isaiah lọ sí ọ̀dọ̀ Hesekiah ọba ó sì béèrè pé, “Kí ni àwọn ènìyàn wọ̀nyí wí, níbo ni wọ́n sì ti wá?” “Láti ilẹ̀ jíjìnnà,” ni èsì Hesekiah. “Wọ́n wá sọ́dọ̀ mi láti Babeli.”
Isaiah 39:3 in English
Isaiah 39:3 · Berean Standard Bible
Then the prophet Isaiah went to King Hezekiah and asked, “Where did those men come from, and what did they say to you?” “They came to me from a distant land,” Hezekiah replied, “from Babylon.”
Context
1Ní àkókò náà ni Merodaki-Baladani ọmọ Baladani ọba Babeli fi ìwé àti ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí Hesekiah, nítorí ó gbọ́ pé ó ṣàìsàn ó sì gbádùn. 2Hesekiah gba àwọn ikọ̀ yìí tayọ̀tayọ̀, ó sì fi àwọn nǹkan tí ó wà nínú yàrá ìkẹ́rù sí mọ́ hàn wọ́n—fàdákà, wúrà, ohun olóòórùn dídùn, òróró dídára, gbogbo nǹkan ogun rẹ̀ àti ohun gbogbo tí ó wà nínú ìṣúra rẹ̀ kò sí ohunkóhun tí ó wà nínú ààfin rẹ̀ tàbí ní ìjọba rẹ̀ tí Hesekiah kò fihàn wọ́n. 3Lẹ́yìn náà wòlíì Isaiah lọ sí ọ̀dọ̀ Hesekiah ọba ó sì béèrè pé, “Kí ni àwọn ènìyàn wọ̀nyí wí, níbo ni wọ́n sì ti wá?”
“Láti ilẹ̀ jíjìnnà,” ni èsì Hesekiah. “Wọ́n wá sọ́dọ̀ mi láti Babeli.” 4Wòlíì náà sì béèrè pé, “Kí ni wọ́n rí nínú ààfin rẹ?”
Hesekiah si dáhùn pe, “Wọ́n rí gbogbo ohun tí ó wà nínú ààfin mi. Kò sí ohun kankan nínú ìṣúra mi tí èmi kò fihàn wọ́n.” 5Lẹ́yìn náà ni Isaiah sọ fún Hesekiah pé, “Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.