Isaiah 38:19
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Alààyè, àwọn alààyè wọ́n ń yìn ọ́, gẹ́gẹ́ bí èmi ti ń ṣe lónìí; àwọn baba sọ fún àwọn ọmọ wọn nípa òtítọ́ rẹ.
Isaiah 38:19 in English
Isaiah 38:19 · Berean Standard Bible
The living, only the living, can thank You, as I do today; fathers will tell their children about Your faithfulness.
Context
17Nítòótọ́ fún àlàáfíà ara mi ni,
ní ti pé mo ní ìkorò ńlá.
Nínú ìfẹ́ rẹ ìwọ pa mí mọ́,
kúrò nínú ọ̀gbun ìparun;
ìwọ sì ti fi gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi sí ẹ̀yìn rẹ. 18Nítorí pé isà òkú kò le è yìn ọ́,
ipò òkú kò le è kọ orin ìyìn rẹ;
àwọn tí ó sọ̀kalẹ̀ sínú ọ̀gbun
kò lè ní ìrètí fún òtítọ́ rẹ. 19Alààyè, àwọn alààyè wọ́n ń yìn ọ́,
gẹ́gẹ́ bí èmi ti ń ṣe lónìí;
àwọn baba sọ fún àwọn ọmọ wọn nípa òtítọ́ rẹ. 20Olúwa yóò gbà mí là
bẹ́ẹ̀ ni àwa yóò sì kọrin pẹ̀lú ohun èlò olókùn
ní gbogbo ọjọ́ ayé wa
nínú tẹmpili ti Olúwa. 21Isaiah ti sọ pé, “Pèsè ìṣù ọ̀pọ̀tọ́ (ohun gbígbóná tí a dì mọ́ ojú egbò) kí o sì fi sí ojú oówo náà, òun yóò sì gbádùn.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.