Isaiah 38:20
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Olúwa yóò gbà mí là bẹ́ẹ̀ ni àwa yóò sì kọrin pẹ̀lú ohun èlò olókùn ní gbogbo ọjọ́ ayé wa nínú tẹmpili ti Olúwa.
Isaiah 38:20 in English
Isaiah 38:20 · Berean Standard Bible
The LORD will save me; we will play songs on stringed instruments all the days of our lives in the house of the LORD.
Context
18Nítorí pé isà òkú kò le è yìn ọ́,
ipò òkú kò le è kọ orin ìyìn rẹ;
àwọn tí ó sọ̀kalẹ̀ sínú ọ̀gbun
kò lè ní ìrètí fún òtítọ́ rẹ. 19Alààyè, àwọn alààyè wọ́n ń yìn ọ́,
gẹ́gẹ́ bí èmi ti ń ṣe lónìí;
àwọn baba sọ fún àwọn ọmọ wọn nípa òtítọ́ rẹ. 20Olúwa yóò gbà mí là
bẹ́ẹ̀ ni àwa yóò sì kọrin pẹ̀lú ohun èlò olókùn
ní gbogbo ọjọ́ ayé wa
nínú tẹmpili ti Olúwa. 21Isaiah ti sọ pé, “Pèsè ìṣù ọ̀pọ̀tọ́ (ohun gbígbóná tí a dì mọ́ ojú egbò) kí o sì fi sí ojú oówo náà, òun yóò sì gbádùn.” 22Hesekiah sì béèrè pé, “Kí ni yóò jẹ́ àmì pé èmi yóò gòkè lọ sí tẹmpili Olúwa?”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.