Isaiah 37:36
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Lẹ́yìn náà ni angẹli Olúwa jáde lọ ó sì pa ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (185,000) ènìyàn ní i ibùdó àwọn Asiria. Nígbà tí àwọn ènìyàn yìí jí ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì gbogbo wọn ti dòkú!
Isaiah 37:36 in English
Isaiah 37:36 · Berean Standard Bible
Then the angel of the LORD went out and struck down 185,000 men in the camp of the Assyrians. When the people got up * the next morning, there were all the dead bodies!
Context
34Nípa ọ̀nà tí ó gbà wá náà ni yóò padà lọ;
òun kì yóò wọ inú ìlú yìí,”
ni Olúwa wí. 35“Èmi yóò dáàbò bo ìlú yìí èmi ó sì gbà á là,
nítorí mi àti nítorí Dafidi ìránṣẹ́ mi!” 36Lẹ́yìn náà ni angẹli Olúwa jáde lọ ó sì pa ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (185,000) ènìyàn ní i ibùdó àwọn Asiria. Nígbà tí àwọn ènìyàn yìí jí ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì gbogbo wọn ti dòkú! 37Nítorí náà Sennakeribu ọba Asiria fọ́ bùdó ó sì pẹsẹ̀dà. Òun sì padà sí Ninefe, ó sì dúró síbẹ̀. 38Ní ọjọ́ kan, bí ó ti ń jọ́sìn nínú tẹmpili Nisroki òrìṣà rẹ̀, àwọn ọmọ rẹ̀ Adrameleki àti Ṣareseri gé e lulẹ̀ pẹ̀lú idà, wọ́n sì sálọ sí ilẹ̀ Ararati. Bẹ́ẹ̀ ni Esarhadoni ọmọ rẹ̀ sì gba ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.