Isaiah 37:25
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi ti gbẹ́ kànga ní ilẹ̀ àjèjì mo sì mu omi ní ibẹ̀, pẹ̀lú àtẹ́lẹsẹ̀ mi Èmi ti gbẹ́ gbogbo omi àwọn odò Ejibiti.’
Isaiah 37:25 in English
Isaiah 37:25 · Berean Standard Bible
I have dug wells and drunk foreign * waters. With the soles of my feet I have dried up all the streams of Egypt.”
Context
23Ta ni ìwọ ti bú tí ìwọ sì ti sọ̀rọ̀-òdì sí?
Sí ta ní ìwọ ti gbé ohùn rẹ sókè
tí o sì gbé ojú rẹ sókè ní ìgbéraga?
Sí Ẹni Mímọ́ Israẹli! 24Nípa àwọn ìránṣẹ́ rẹ,
ìwọ ti sọ̀rọ̀ búburú sí Olúwa.
Tì wọ sì wí pé,
‘Pẹ̀lú ọ̀pọ̀ kẹ̀kẹ́ mi
ni èmi sì fi dé orí àwọn òkè ńlá,
sí ibi gíga jùlọ Lebanoni.
Èmi a sì ké igi kedari gíga rẹ̀ lulẹ̀,
àti ààyò igi firi rẹ̀.
Èmi ti dé ibi rẹ̀ tí ó ga jùlọ,
igbó rẹ̀ tí ó dára jùlọ. 25Èmi ti gbẹ́ kànga ní ilẹ̀ àjèjì
mo sì mu omi ní ibẹ̀,
pẹ̀lú àtẹ́lẹsẹ̀ mi
Èmi ti gbẹ́ gbogbo omi àwọn odò Ejibiti.’ 26“Ṣé o kò tí ì gbọ́?
Tipẹ́tipẹ́ ni mo ti fìdí rẹ̀ mulẹ̀.
Láti ìgbà pípẹ́ ni mo ti ṣètò rẹ̀;
ní àkókò yìí ni mo mú wá sí ìmúṣẹ,
pé o ti sọ àwọn ìlú olódi di
àkójọpọ̀ àwọn òkúta. 27Àwọn ènìyàn, tí agbára ti wọ̀ lẹ́wù,
ni wọ́n banújẹ́ tí a sì dójútì.
Wọ́n dàbí ohun ọ̀gbìn nínú pápá,
gẹ́gẹ́ bí ọ̀jẹ̀lẹ̀ èhíhù tuntun,
gẹ́gẹ́ bí i koríko tí ó ń hù lórí òrùlé,
tí ó jóná kí ó tó dàgbàsókè.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.