Isaiah 37:22
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa ti sọ nípa rẹ̀: “Wúńdíá ọmọbìnrin Sioni ti kẹ́gàn rẹ, ó sì ti fi ọ ṣe ẹlẹ́yà. Ọmọbìnrin Jerusalẹmu ti mi orí rẹ̀ bí ó ti ń sálọ.
Isaiah 37:22 in English
Isaiah 37:22 · Berean Standard Bible
this is the word that the LORD has spoken against him: ‘The Virgin Daughter of Zion despises you and mocks you; the Daughter of Jerusalem shakes her head behind you.
Context
20Nísinsin yìí, ìwọ Olúwa, Ọlọ́run wa, gbà wá lọ́wọ́ rẹ̀, tí ó fi jẹ́ pé gbogbo ìjọba ilẹ̀ ayé yóò fi mọ̀ pé Ìwọ, Ìwọ nìkan, Olúwa ni Ọlọ́run.” 21Lẹ́yìn náà Isaiah ọmọ Amosi rán iṣẹ́ kan sí Hesekiah: “Èyí ni ohun tí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli sọ pé, nítorí pé ìwọ ti gbàdúrà sí mi nípa Sennakeribu ọba Asiria, 22èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa ti sọ nípa rẹ̀:
“Wúńdíá ọmọbìnrin Sioni
ti kẹ́gàn rẹ, ó sì ti fi ọ ṣe ẹlẹ́yà.
Ọmọbìnrin Jerusalẹmu
ti mi orí rẹ̀ bí ó ti ń sálọ. 23Ta ni ìwọ ti bú tí ìwọ sì ti sọ̀rọ̀-òdì sí?
Sí ta ní ìwọ ti gbé ohùn rẹ sókè
tí o sì gbé ojú rẹ sókè ní ìgbéraga?
Sí Ẹni Mímọ́ Israẹli! 24Nípa àwọn ìránṣẹ́ rẹ,
ìwọ ti sọ̀rọ̀ búburú sí Olúwa.
Tì wọ sì wí pé,
‘Pẹ̀lú ọ̀pọ̀ kẹ̀kẹ́ mi
ni èmi sì fi dé orí àwọn òkè ńlá,
sí ibi gíga jùlọ Lebanoni.
Èmi a sì ké igi kedari gíga rẹ̀ lulẹ̀,
àti ààyò igi firi rẹ̀.
Èmi ti dé ibi rẹ̀ tí ó ga jùlọ,
igbó rẹ̀ tí ó dára jùlọ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.