Isaiah 37:21
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Lẹ́yìn náà Isaiah ọmọ Amosi rán iṣẹ́ kan sí Hesekiah: “Èyí ni ohun tí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli sọ pé, nítorí pé ìwọ ti gbàdúrà sí mi nípa Sennakeribu ọba Asiria,
Isaiah 37:21 in English
Isaiah 37:21 · Berean Standard Bible
Then Isaiah son of Amoz sent a message to Hezekiah: “This is what the LORD, the God of Israel, says: Because you have prayed to Me concerning Sennacherib king of Assyria,
Context
19Wọ́n ti da àwọn òrìṣà wọn sínú iná wọ́n sì ti pa wọ́n run, nítorí àwọn wọ̀nyí kì í ṣe ọlọ́run bí kò ṣe igi àti òkúta lásán, tí a ti ọwọ́ ènìyàn ṣe. 20Nísinsin yìí, ìwọ Olúwa, Ọlọ́run wa, gbà wá lọ́wọ́ rẹ̀, tí ó fi jẹ́ pé gbogbo ìjọba ilẹ̀ ayé yóò fi mọ̀ pé Ìwọ, Ìwọ nìkan, Olúwa ni Ọlọ́run.” 21Lẹ́yìn náà Isaiah ọmọ Amosi rán iṣẹ́ kan sí Hesekiah: “Èyí ni ohun tí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli sọ pé, nítorí pé ìwọ ti gbàdúrà sí mi nípa Sennakeribu ọba Asiria, 22èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa ti sọ nípa rẹ̀:
“Wúńdíá ọmọbìnrin Sioni
ti kẹ́gàn rẹ, ó sì ti fi ọ ṣe ẹlẹ́yà.
Ọmọbìnrin Jerusalẹmu
ti mi orí rẹ̀ bí ó ti ń sálọ. 23Ta ni ìwọ ti bú tí ìwọ sì ti sọ̀rọ̀-òdì sí?
Sí ta ní ìwọ ti gbé ohùn rẹ sókè
tí o sì gbé ojú rẹ sókè ní ìgbéraga?
Sí Ẹni Mímọ́ Israẹli!
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.