Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“ ‘Ẹ wá nísinsin yìí, bá ọ̀gá mi pa ìmọ̀ pọ̀, ọba Asiria, èmi yóò fún ọ ní ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ẹṣin bí ìwọ bá le è fi agẹṣin lé wọn lórí!

Isaiah 36:8 in English

Isaiah 36:8 · Berean Standard Bible

Now, therefore, make a bargain with my master, the king of Assyria. I will give you two thousand horses—if you can put riders on them!

Context

6Wò ó nísinsin yìí, ìwọ gbẹ́kẹ̀lé Ejibiti ẹ̀rún igi ọ̀pá lásán tí í gún ni lọ́wọ́ tí í sì í dọ́gbẹ́ sí ni lára tí a bá gbára lé e! Bẹ́ẹ̀ ni Farao ọba Ejibiti sí àwọn tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé e. 7Bí o bá sì sọ fún mi pé, “Àwa gbẹ́kẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run wa,” kì í ṣe òun ni Hesekiah ti mú àwọn ibi gíga àti pẹpẹ rẹ̀ kúrò, tí ó sì wí fún Juda àti Jerusalẹmu pé, “Ẹ̀yin gbọdọ̀ sìn níwájú pẹpẹ yìí”? 8“ ‘Ẹ wá nísinsin yìí, bá ọ̀gá mi pa ìmọ̀ pọ̀, ọba Asiria, èmi yóò fún ọ ní ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ẹṣin bí ìwọ bá le è fi agẹṣin lé wọn lórí! 9Báwo ni ẹ ṣe lè lé ẹyọ kan ṣoṣo padà nínú èyí tí ó kéré jù nínú àwọn balógun olúwa mi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ gbẹ́kẹ̀lé Ejibiti fún kẹ̀kẹ́-ẹṣin àti àwọn ẹlẹ́ṣin? 10Síwájú sí i, ǹjẹ́ mo wa lè wá bá ilẹ̀ yìí jà kí n sì pa á run láìsí Olúwa? Olúwa fún rara rẹ̀ ló sọ pé kí n bá orílẹ̀-èdè yìí jà kí n sì pa á run.’ ”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.