Isaiah 36:7
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bí o bá sì sọ fún mi pé, “Àwa gbẹ́kẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run wa,” kì í ṣe òun ni Hesekiah ti mú àwọn ibi gíga àti pẹpẹ rẹ̀ kúrò, tí ó sì wí fún Juda àti Jerusalẹmu pé, “Ẹ̀yin gbọdọ̀ sìn níwájú pẹpẹ yìí”?
Isaiah 36:7 in English
Isaiah 36:7 · Berean Standard Bible
But if you say to me, ‘We trust in the LORD our God,’ is He not the One whose high places and altars Hezekiah has removed, saying to Judah and Jerusalem, ‘You must worship before this altar’?
Context
5Ìwọ sọ wí pé ìwọ ní ète àti agbára ogun—ṣùgbọ́n ìwọ ń sọ ọ̀rọ̀ asán. Ta ni ìwọ gbẹ́kẹ̀lé tí ìwọ fi ṣọ̀tẹ̀ sí mi? 6Wò ó nísinsin yìí, ìwọ gbẹ́kẹ̀lé Ejibiti ẹ̀rún igi ọ̀pá lásán tí í gún ni lọ́wọ́ tí í sì í dọ́gbẹ́ sí ni lára tí a bá gbára lé e! Bẹ́ẹ̀ ni Farao ọba Ejibiti sí àwọn tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé e. 7Bí o bá sì sọ fún mi pé, “Àwa gbẹ́kẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run wa,” kì í ṣe òun ni Hesekiah ti mú àwọn ibi gíga àti pẹpẹ rẹ̀ kúrò, tí ó sì wí fún Juda àti Jerusalẹmu pé, “Ẹ̀yin gbọdọ̀ sìn níwájú pẹpẹ yìí”? 8“ ‘Ẹ wá nísinsin yìí, bá ọ̀gá mi pa ìmọ̀ pọ̀, ọba Asiria, èmi yóò fún ọ ní ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ẹṣin bí ìwọ bá le è fi agẹṣin lé wọn lórí! 9Báwo ni ẹ ṣe lè lé ẹyọ kan ṣoṣo padà nínú èyí tí ó kéré jù nínú àwọn balógun olúwa mi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ gbẹ́kẹ̀lé Ejibiti fún kẹ̀kẹ́-ẹṣin àti àwọn ẹlẹ́ṣin?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.