Isaiah 36:6
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wò ó nísinsin yìí, ìwọ gbẹ́kẹ̀lé Ejibiti ẹ̀rún igi ọ̀pá lásán tí í gún ni lọ́wọ́ tí í sì í dọ́gbẹ́ sí ni lára tí a bá gbára lé e! Bẹ́ẹ̀ ni Farao ọba Ejibiti sí àwọn tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé e.
Isaiah 36:6 in English
Isaiah 36:6 · Berean Standard Bible
Look now, you are trusting in Egypt, that splintered reed of a staff that will pierce the hand of anyone who leans on it. Such is Pharaoh king of Egypt to all who trust in him.
Context
4Ọ̀gágun náà sọ fún wọn wí pé, “Ẹ sọ fún Hesekiah,
“ ‘Èyí yìí ni ohun tí ọba ńlá, ọba Asiria sọ pé: Lórí i kí ni ìwọ gbé ìgbẹ́kẹ̀lé tìrẹ yìí lé? 5Ìwọ sọ wí pé ìwọ ní ète àti agbára ogun—ṣùgbọ́n ìwọ ń sọ ọ̀rọ̀ asán. Ta ni ìwọ gbẹ́kẹ̀lé tí ìwọ fi ṣọ̀tẹ̀ sí mi? 6Wò ó nísinsin yìí, ìwọ gbẹ́kẹ̀lé Ejibiti ẹ̀rún igi ọ̀pá lásán tí í gún ni lọ́wọ́ tí í sì í dọ́gbẹ́ sí ni lára tí a bá gbára lé e! Bẹ́ẹ̀ ni Farao ọba Ejibiti sí àwọn tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé e. 7Bí o bá sì sọ fún mi pé, “Àwa gbẹ́kẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run wa,” kì í ṣe òun ni Hesekiah ti mú àwọn ibi gíga àti pẹpẹ rẹ̀ kúrò, tí ó sì wí fún Juda àti Jerusalẹmu pé, “Ẹ̀yin gbọdọ̀ sìn níwájú pẹpẹ yìí”? 8“ ‘Ẹ wá nísinsin yìí, bá ọ̀gá mi pa ìmọ̀ pọ̀, ọba Asiria, èmi yóò fún ọ ní ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ẹṣin bí ìwọ bá le è fi agẹṣin lé wọn lórí!
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.