Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà náà ni a ó la ojú àwọn afọ́jú àti etí àwọn odi kì yóò dákẹ́.

Isaiah 35:5 in English

Isaiah 35:5 · Berean Standard Bible

Then the eyes of the blind will be opened and the ears of the deaf unstopped.

Context

3Fún ọwọ́ àìlera lókun, mú orúnkún tí ń yẹ̀ lókun. 4Sọ fún àwọn oníbẹ̀rù ọkàn pé, “Ẹ ṣe gírí, ẹ má bẹ̀rù; Ọlọ́run yín yóò wá, òun yóò wá pẹ̀lú ìgbẹ̀san; pẹ̀lú ìgbẹ̀san mímọ́ òun yóò wá láti gbà yín là.” 5Nígbà náà ni a ó la ojú àwọn afọ́jú àti etí àwọn odi kì yóò dákẹ́. 6Nígbà náà ni àwọn arọ yóò máa fò bí àgbọ̀nrín, àti ahọ́n odi yóò ké fún ayọ̀. Odò yóò tú jáde nínú aginjù àti àwọn odò nínú aṣálẹ̀. 7Ilẹ̀ iyanrìn yíyan yóò di àbàtà, ilẹ̀ tí ń pòǹgbẹ yóò di orísun omi. Ní ibùgbé àwọn dragoni, níbi tí olúkúlùkù dùbúlẹ̀, ni ó jẹ́ ọgbà fún eèsún àti papirusi.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.