Isaiah 34:5
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí ti a rẹ idà mi ní ọ̀run, kíyèsi í, yóò sọ̀kalẹ̀ wá sórí Edomu, sórí àwọn ènìyàn tí mo ti parun fún ìdájọ́.
Isaiah 34:5 in English
Isaiah 34:5 · Berean Standard Bible
When My sword has drunk its fill in the heavens, then it will come down upon Edom, upon the people I have devoted to destruction.
Context
3Àwọn ti a pa nínú wọn
ni a ó sì jù sóde,
òórùn wọn yóò ti inú òkú wọn jáde,
àwọn òkè ńlá yóò sì yọ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ wọn. 4Gbogbo àwọn ogun ọ̀run ni yóò di yíyọ́,
a ó sì ká àwọn ọ̀run jọ bí i tákàdá,
gbogbo ogun wọn yóò si ṣubú lulẹ̀,
bí ewé ti n bọ́ kúrò lára àjàrà,
àti bí i bíbọ́ èso lára igi ọ̀pọ̀tọ́. 5Nítorí ti a rẹ idà mi ní ọ̀run,
kíyèsi í, yóò sọ̀kalẹ̀ wá sórí Edomu,
sórí àwọn ènìyàn tí mo ti parun fún ìdájọ́. 6Idà Olúwa kún fún ẹ̀jẹ̀
a mú un sanra fún ọ̀rá,
àti fún ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́-àgùntàn àti ewúrẹ́,
fún ọ̀rá ìwé àgbò—
nítorí Olúwa ni ìrúbọ kan ní Bosra,
àti ìpakúpa ńlá kan ní ilẹ̀ Edomu. 7Àti àwọn àgbáǹréré yóò
ba wọn sọ̀kalẹ̀ wá,
àti àwọn ẹgbọrọ màlúù
pẹ̀lú àwọn akọ màlúù,
ilé wọn ni a ó fi ẹ̀jẹ̀ rin,
a ó sì fi ọ̀rá sọ ekuru wọn di ọlọ́ràá.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.