Isaiah 33:22
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí Olúwa ni onídàájọ́ wa, Olúwa ni onídàájọ́ wa, Olúwa òun ni ọba wa; òun ni ẹni tí yóò gbà wá là.
Isaiah 33:22 in English
Isaiah 33:22 · Berean Standard Bible
For the LORD is our Judge, the LORD is our lawgiver, the LORD is our King. It is He who will save us.
Context
20Gbójú sókè sí Sioni, ìlú àjọ̀dún wa,
ojú rẹ yóò rí Jerusalẹmu,
ibùgbé àlàáfíà n nì, àgọ́ tí a kò ní yí padà;
àwọn òpó rẹ̀ ni a kì yóò fàtu
tàbí èyíkéyìí nínú okùn rẹ̀ kí já. 21Níbẹ̀ ni Olúwa yóò ti jẹ́ alágbára kan fún wa.
Yóò sì dàbí ibi àwọn odò ńlá ńlá àti odò kéékèèké.
Kì yóò sí ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú tí yóò kọjá lórí i wọn,
ọkọ̀ ojú omi ńlá ni a kì yóò tù lórí wọn. 22Nítorí Olúwa ni onídàájọ́ wa,
Olúwa ni onídàájọ́ wa,
Olúwa òun ni ọba wa;
òun ni ẹni tí yóò gbà wá là. 23Gbogbo okùn rẹ ni ó ti dẹ̀:
Ìgbókùnró kò fìdímúlẹ̀,
wọn kò taṣọ agbọ́kọ̀rìn,
lẹ́yìn náà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìkógun ni a ó pín
àní arọ pẹ̀lú yóò ru ìkógun lọ. 24Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó ń gbé Sioni tí yóò wí pé, “Ara mi kò yá,”
a ó dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn tí ń gbé ibẹ̀ jì wọ́n.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.