Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Níbẹ̀ ni Olúwa yóò ti jẹ́ alágbára kan fún wa. Yóò sì dàbí ibi àwọn odò ńlá ńlá àti odò kéékèèké. Kì yóò sí ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú tí yóò kọjá lórí i wọn, ọkọ̀ ojú omi ńlá ni a kì yóò tù lórí wọn.

Isaiah 33:21 in English

Isaiah 33:21 · Berean Standard Bible

But there the Majestic One, our LORD, will be for us a place of rivers and wide canals, where no galley with oars will row, and no majestic vessel will pass.

Context

19Ìwọ kì yóò rí àwọn agbéraga ènìyàn mọ́, àwọn ènìyàn tí èdè wọn fi ara sin, pẹ̀lú ahọ́n tí ó ṣàjèjì tí kò sì yé ni. 20Gbójú sókè sí Sioni, ìlú àjọ̀dún wa, ojú rẹ yóò rí Jerusalẹmu, ibùgbé àlàáfíà n nì, àgọ́ tí a kò ní yí padà; àwọn òpó rẹ̀ ni a kì yóò fàtu tàbí èyíkéyìí nínú okùn rẹ̀ kí já. 21Níbẹ̀ ni Olúwa yóò ti jẹ́ alágbára kan fún wa. Yóò sì dàbí ibi àwọn odò ńlá ńlá àti odò kéékèèké. Kì yóò sí ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú tí yóò kọjá lórí i wọn, ọkọ̀ ojú omi ńlá ni a kì yóò tù lórí wọn. 22Nítorí Olúwa ni onídàájọ́ wa, Olúwa ni onídàájọ́ wa, Olúwa òun ni ọba wa; òun ni ẹni tí yóò gbà wá là. 23Gbogbo okùn rẹ ni ó ti dẹ̀: Ìgbókùnró kò fìdímúlẹ̀, wọn kò taṣọ agbọ́kọ̀rìn, lẹ́yìn náà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìkógun ni a ó pín àní arọ pẹ̀lú yóò ru ìkógun lọ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.