Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

sí Ejibiti tí ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ kò wúlò rárá. Nítorí náà mo pè é ní Rahabu aláìlẹ́ṣẹ̀ nǹkan kan.

Isaiah 30:7 in English

Isaiah 30:7 · Berean Standard Bible

Egypt’s help is futile and empty; therefore I have called her Rahab Who Sits Still.*

Context

5gbogbo wọn ni a ó dójútì, nítorí àwọn ènìyàn kan tí kò wúlò fún wọn, tí kò mú ìrànlọ́wọ́ tàbí àǹfààní wá, bí kò ṣe àbùkù àti ìdójúti ni.” 6Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ sí àwọn ẹranko tí ó wà ní gúúsù. Láàrín ilẹ̀ ìnira àti ìpọ́njú, ti kìnnìún àti abo kìnnìún ti paramọ́lẹ̀ àti ejò olóró, àwọn ikọ̀ náà kó ẹrù àti ọrọ̀ wọn lẹ́yìn àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àwọn ohun ìní wọn ní orí àwọn ìbákasẹ, sí orílẹ̀-èdè aláìlérè, 7sí Ejibiti tí ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ kò wúlò rárá. Nítorí náà mo pè é ní Rahabu aláìlẹ́ṣẹ̀ nǹkan kan. 8Lọ nísinsin yìí, kí o sì kọ ọ́ sí ara wàláà fún wọn, tẹ̀ ẹ́ sí ara ìwé kíká, pé fún àwọn ọjọ́ tí ó ń bọ̀ kí ó sì lè jẹ́ ẹ̀rí ayérayé. 9Àwọn wọ̀nyí jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn àti ẹlẹ́tanu ọmọ, àwọn ọmọ tí wọn kò ṣetán láti tẹ́tí sí ìtọ́ni Olúwa.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.