Isaiah 3:6
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọkùnrin kan yóò di ọ̀kan nínú àwọn arákùnrin rẹ̀ mú, nínú ilé baba rẹ̀, yóò sì wí pé, “Ìwọ́ ní aṣọ, ìwọ máa ṣe olórí wa, sì mójútó àwọn ahoro wọ̀nyí!”
Isaiah 3:6 in English
Isaiah 3:6 · Berean Standard Bible
A man will seize his brother within his father’s house: “You have a cloak—you be our leader! Take charge of this heap of rubble.”
Context
4“Èmi ó sọ àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin di aláṣẹ wọn,
ọ̀dọ́mọdé lásán làsàn ni yóò sì
máa jẹ ọba lórí i wọn.” 5Àwọn ènìyàn yóò sì máa pọ́n ọmọnìkejì,
wọn lójú ẹnìkan sí ẹnìkejì rẹ̀, aládùúgbò sí aládùúgbò rẹ̀.
Àwọn ọ̀dọ́ yóò gbógun ti àwọn àgbàgbà,
àwọn mẹ̀kúnnù yóò dìde sí ọlọ́lá. 6Ọkùnrin kan yóò di ọ̀kan nínú àwọn
arákùnrin rẹ̀ mú,
nínú ilé baba rẹ̀, yóò sì wí pé,
“Ìwọ́ ní aṣọ, ìwọ máa ṣe olórí wa,
sì mójútó àwọn ahoro wọ̀nyí!” 7Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ náà ni yóò figbe bọnu pé,
“Èmi kò ní àtúnṣe kan.
Èmi kò ní oúnjẹ, bẹ́ẹ̀ ni n ó ní aṣọ nílé,
ẹ má fi mí ṣe olórí àwọn ènìyàn náà.” 8Jerusalẹmu ń ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n
Juda ń ṣubú lọ,
ọ̀rọ̀ àti ìṣe wọn lòdì sí Olúwa,
láti mú ojú ògo rẹ̀ bínú.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.