Isaiah 29:2
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Síbẹ̀síbẹ̀ èmi yóò dó ti Arieli òun yóò ṣọ̀fọ̀ yóò sì sọkún, òun yóò sì dàbí pẹpẹ ọkàn sí mi.
Isaiah 29:2 in English
Isaiah 29:2 · Berean Standard Bible
And I will constrain Ariel, and there will be mourning and lamentation; she will be like an altar hearth * before Me.
Context
1Ègbé ni fún ọ, Arieli, Arieli,
ìlú níbi tí Dafidi tẹ̀dó sí!
Fi ọdún kún ọdún
sì jẹ́ kí àwọn àkọlùkọgbà àjọ̀dún un rẹ tẹ̀síwájú. 2Síbẹ̀síbẹ̀ èmi yóò dó ti Arieli
òun yóò ṣọ̀fọ̀ yóò sì sọkún,
òun yóò sì dàbí pẹpẹ ọkàn sí mi. 3Èmi yóò sì wà ní bùba yí ọ ká níbi gbogbo,
Èmi yóò sì fi ilé ìṣọ́ yí ọ ká,
Èmi yóò sì fi iṣẹ́ ìdó ti ni mi dojúkọ ọ́. 4Ní ìrẹ̀sílẹ̀, ìwọ ó sì máa sọ̀rọ̀ láti ilẹ̀ wá;
ọ̀rọ̀ rẹ yóò sì máa kùn jáde láti inú erùpẹ̀.
Ohun rẹ yóò máa jáde bí i ti ẹnìkan tó ní ẹ̀mí àfọ̀ṣẹ láti ilẹ̀ jáde wá,
láti inú erùpẹ̀ ni ohùn rẹ
yóò máa wá wúyẹ́wúyẹ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.