Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí òun bá ti tẹ́ ojú ilẹ̀ rẹ̀ pẹrẹsẹ òun kò ha ń fúnrúgbìn dílì kí ó sì fúnrúgbìn kummini ká? Kí ó sì gbin alikama lẹ́sẹẹsẹ, barle tí a yàn, àti spelti ní ipò rẹ̀?

Isaiah 28:25 in English

Isaiah 28:25 · Berean Standard Bible

When he has leveled its surface, does he not sow caraway and scatter cumin? He plants wheat in rows and barley in plots, and rye within its border.

Context

23Tẹ́tí kí o sì gbọ́ ohùn mi, fi ara balẹ̀ kí o sì gbọ́ ohun tí mo sọ. 24Nígbà tí àgbẹ̀ kan bá tu ilẹ̀ láti gbìn yóò ha máa tulẹ̀ títí bi? Ǹjẹ́ yóò ha máa tu ilẹ̀ kí ó sì máa jọ̀ ọ́ títí lọ bí? 25Nígbà tí òun bá ti tẹ́ ojú ilẹ̀ rẹ̀ pẹrẹsẹ òun kò ha ń fúnrúgbìn dílì kí ó sì fúnrúgbìn kummini ká? Kí ó sì gbin alikama lẹ́sẹẹsẹ, barle tí a yàn, àti spelti ní ipò rẹ̀? 26Ọlọ́run rẹ̀ tọ́ ọ ṣọ́nà ó sì kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ ní ọ̀nà tó tọ́. 27Nítorí a kò fi ohun èlò ìpakà dili, bẹ́ẹ̀ ni a kì í yí kẹ̀kẹ́ ẹrù kiri lórí kummini; ṣùgbọ́n ọ̀pá ni a fi ń pa dili jáde, ọ̀gọ ni a sì lu kummini.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.