Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Tẹ́tí kí o sì gbọ́ ohùn mi, fi ara balẹ̀ kí o sì gbọ́ ohun tí mo sọ.

Isaiah 28:23 in English

Isaiah 28:23 · Berean Standard Bible

Listen and hear my voice. Pay attention and hear what I say.

Context

21Olúwa yóò dìde sókè gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ní òkè Perasimu yóò ru ara rẹ̀ sókè gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ní àfonífojì Gibeoni— láti ṣe iṣẹ́ rẹ̀, abàmì iṣẹ́ ẹ rẹ̀, yóò ṣe iṣẹ́ rẹ̀, àní àjèjì iṣẹ́ rẹ̀. 22Ní ìsinsin yìí ẹ dákẹ́ ẹlẹ́yà ṣíṣe, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ ìdè e yín yóò le sí i; Olúwa, àní Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti sọ fún mi nípa àṣẹ ìparun ti ó ti pa lórí gbogbo ilẹ̀ náà. 23Tẹ́tí kí o sì gbọ́ ohùn mi, fi ara balẹ̀ kí o sì gbọ́ ohun tí mo sọ. 24Nígbà tí àgbẹ̀ kan bá tu ilẹ̀ láti gbìn yóò ha máa tulẹ̀ títí bi? Ǹjẹ́ yóò ha máa tu ilẹ̀ kí ó sì máa jọ̀ ọ́ títí lọ bí? 25Nígbà tí òun bá ti tẹ́ ojú ilẹ̀ rẹ̀ pẹrẹsẹ òun kò ha ń fúnrúgbìn dílì kí ó sì fúnrúgbìn kummini ká? Kí ó sì gbin alikama lẹ́sẹẹsẹ, barle tí a yàn, àti spelti ní ipò rẹ̀?

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.