Isaiah 28:20
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ibùsùn kúrú púpọ̀ fún ìnara lé lórí, ìbora kò fẹ̀ tó láti yí ara yín ká.
Isaiah 28:20 in English
Isaiah 28:20 · Berean Standard Bible
Indeed, the bed is too short to stretch out on, and the blanket too small to wrap around you.
Context
18Májẹ̀mú yín tí ẹ bá ikú dá ni a ó fa igi lé;
àdéhùn yín pẹ̀lú ibojì ni kì yóò dúró.
Nígbà tí ìbínú gbígbóná náà bá fẹ́ kọjá,
a ó ti ipa rẹ̀ lù yín bolẹ̀. 19Nígbàkígbà tí ó bá ti wá ni
yóò máa gbé ọ lọ,
ni àràárọ̀, ní ọ̀sán àti ní òru,
ni yóò máa fẹ́ kọjá lọ.”
Ìmòye ọ̀rọ̀-ìmọ̀ yìí
yóò máa mú ìpayà ńlá wá. 20Ibùsùn kúrú púpọ̀ fún ìnara lé lórí,
ìbora kò fẹ̀ tó láti yí ara yín ká. 21Olúwa yóò dìde sókè gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe
ní òkè Perasimu
yóò ru ara rẹ̀ sókè gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe
ní àfonífojì Gibeoni—
láti ṣe iṣẹ́ rẹ̀, abàmì iṣẹ́ ẹ rẹ̀,
yóò ṣe iṣẹ́ rẹ̀, àní àjèjì iṣẹ́ rẹ̀. 22Ní ìsinsin yìí ẹ dákẹ́ ẹlẹ́yà ṣíṣe,
bí bẹ́ẹ̀ kọ́ ìdè e yín yóò le sí i;
Olúwa, àní Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti sọ fún mi
nípa àṣẹ ìparun ti ó ti pa lórí gbogbo ilẹ̀ náà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.