Isaiah 26:13
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Olúwa Ọlọ́run wa, àwọn olúwa mìíràn lẹ́yìn rẹ ti jẹ ọba lé wa lórí, ṣùgbọ́n orúkọ rẹ nìkan ni àwa fi ọ̀wọ̀ fún.
Isaiah 26:13 in English
Isaiah 26:13 · Berean Standard Bible
O LORD our God, other lords besides You have had dominion, but Your name alone do we confess.
Context
11Olúwa, ti gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè
ṣùgbọ́n àwọn kò rí i.
Jẹ́ kí wọ́n rí ìtara rẹ fún àwọn ènìyàn rẹ
kí ojú kí ó tì wọ́n;
jẹ́ kí iná tí a fi pamọ́ fún àwọn
ọ̀tá rẹ jó wọn run. 12Olúwa, ìwọ fi àlàáfíà lélẹ̀ fún wa;
ohun gbogbo tí a ti ṣe yọrí ìwọ ni
ó ṣe é fún wa. 13Olúwa Ọlọ́run wa, àwọn olúwa mìíràn
lẹ́yìn rẹ ti jẹ ọba lé wa lórí,
ṣùgbọ́n orúkọ rẹ nìkan ni àwa fi ọ̀wọ̀ fún. 14Wọ́n ti kú báyìí, wọn ò sí láààyè mọ́;
gbogbo ẹ̀mí tí ó ti kọjá lọ wọ̀nyí kò le dìde mọ́.
Ìwọ jẹ́ wọ́n ní ìyà o sì sọ wọ́n di asán,
ìwọ pa gbogbo ìrántí wọn rẹ́ pátápátá. 15Ìwọ ti mú orílẹ̀-èdè gbòòrò, Olúwa;
ìwọ ti mú orílẹ̀-èdè bí sí i.
Ìwọ ti gba ògo fún ara rẹ;
ìwọ ti sún gbogbo àwọn ààlà ilẹ̀ sẹ́yìn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.