Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní orí òkè yìí ni yóò pa aṣọ òkú tí ó ti ń di gbogbo ènìyàn, abala tí ó bo gbogbo orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀,

Isaiah 25:7 in English

Isaiah 25:7 · Berean Standard Bible

On this mountain He will swallow up the shroud that enfolds all peoples, the sheet that covers all nations;

Context

5àti gẹ́gẹ́ bí ooru ní aginjù. O mú ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ bá rògbòdìyàn àwọn àjèjì, gẹ́gẹ́ bí òjìji kurukuru ṣe ń dín ooru kù, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni orin àwọn ìkà yóò dákẹ́. 6Ní orí òkè yìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò ti pèsè àsè oúnjẹ àdídùn kan fún gbogbo ènìyàn àpèjẹ ti ọtí wáìnì àtijọ́ ti ẹran tí ó dára jù àti ti ọtí wáìnì tí ó gbámúṣé. 7Ní orí òkè yìí ni yóò pa aṣọ òkú tí ó ti ń di gbogbo ènìyàn, abala tí ó bo gbogbo orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀, 8Òun yóò sì gbé ikú mì títí láé. Olúwa Olódùmarè yóò sì nu gbogbo omijé nù, kúrò ní ojú gbogbo wọn, Òun yóò sì mú ẹ̀gàn àwọn ènìyàn rẹ̀ kúrò ní gbogbo ilẹ̀ ayé. Olúwa ni ó ti sọ ọ́. 9Ní ọjọ́ náà wọn yóò sọ pé, “Nítòótọ́ eléyìí ni Ọlọ́run wa; àwa ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ̀, òun sì gbà wá là. Èyí ni Olúwa, àwa gbẹ́kẹ̀lé e, ẹ jẹ́ kí a yọ̀ kí inú wa sì dùn nínú ìgbàlà rẹ̀.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.